Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Òṣèlú PDP Se Ìfilọ́lẹ̀ Ìpolongo Ètò Ìbò Ní Ìpínlẹ̀ Kano

0 198

 

Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP se ìfilọ́lẹ̀ Ìpolongo èto Ìbò ní Ìpínlè Kano, ìwọ̀ Oòrùn Àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí wọn syì gbé àsìá ẹgbẹ́ fún àwọn olùkópa kọ̀ọ̀kan tí wọn ńlọ fún ipò kan tàbí òmíràn nínú ẹgbẹ́ látàrí ìbò ọdún tó n bọ̀

Olùdíje Gómìnà ní ìpínlẹ̀ náà, Sadik Aminu Wali àti Igbákejì rẹ̀, Yusuf Bello Danbatta ni ẹgbẹ́ gbé àsìá fún. Ẹgbẹ tún rántí àwọn mẹ́ta míràn tí wọ́n ńlọ fún ipò Senatọ̀ , àwọn mẹ́rìnlélógún tó n lọ fún ilé asojú àti ogójì tó ń lọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin


Sénétọ̀ tó ń sojú fún àárín gbùngbùn Kano Mallam Ibrahim Shekarau, ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ níyànjú pé kí wọ́n dúró déédé, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ takuntakun fún àṣeyọrí ẹgbe ní ìpínlẹ̀ Kano.

Ọpọlọpọ adari ẹgbẹ́ ló péjú pésẹ̀ sí ibi ayẹyẹ náà bíi: Senatọ̀ Bello Hayatu Gwarzo, Igbákejì alága PDP agbègbè iwọ̀ oorun Ariwa, Komisọ́na tẹ́lẹ̀ rí ti àlùmọ́nì omi ní ìpínlẹ̀ Kano, Dr. Yunusa Adamu Dangwani; àti Komisọ́na tẹ́lẹ̀ rí ìròyìn , Prof. Umar Faruq àti ọ̀pọ̀ adari ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ Kano.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Ti

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button