Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde ti gba gbogbo lọkọ laya níyànjú lati ta kete sí a n ṣe àfiwé ìgbéyàwó nítorí kò sí ìgbéyàwó kan tó dàbí òmíràn.
Gómìnà ẹni tí ó sísọ lójú ọrọ yìí ni ilé ìjósìn (Anglican Communion) Church of the Transfiguration, to kalẹ sí àgbègbè Ikolaba, ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú ìpínlè Ọ̀yọ́ ni ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà, nibi tí o ti péjú láti bá ìdílé Agbẹjọro Agba Otunba Kunle Kalejaye ṣe ìsìn idupẹ igbeyawo omokunrin rẹ Ilésanmí Oyinlola Kalejaye ati Olayinka tíì ṣe iyawo rẹ.
Makinde, ẹni tí o salaye wípé ọpọlọpọ ìgbéyàwó lóde òní ló ti túká nitori pé àwọn lọkọ laya n gbé ìgbéyàwó wọn lori igbelewon àwọn ẹlòmíràn eléyìí tí agbára wọn kò gbé.
Gómìnà Makinde nínú ọrọ rẹ jẹ kí o di mímọ pé òun náà ti wa nínú ìrìn àjò loko laya pelu ìyàwó rẹ lati bíi ọdún meedogbon sẹyìn, tó sì sàlàyé pe òun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbéyàwó ni ki ọkọ ati ìyàwó nii lọkàn wípé kòsí ìgbéyàwó méjì to jo ara wọn. O wa gba awọn ọkọ ati ìyàwó náà níyànjú láti máṣe afarawe nitori ọpọlọpọ ìdílé ló ti daru latari afarawe. O sì gbàá l’adura ki wọn ni ibagbepo alaseyori, ki Eledua sí ṣe wón ní ọrẹ ara wọn dalẹ
Ṣáájú nínú ìwàásù rẹ ni Bisọọbu Joshua Oyinlola ti ilé ìjósìn irelle Ese Odo ni ipinlẹ Ondo ti fi àsìkò náà rawọ ẹbẹ sí ìjoba apapo lati fi eti sí ìbéèrè àwọn ẹgbẹ olukọ ile ẹkọ gíga fasiti (ASUU) ki irú iyanselodi olosu mẹjọ to wáyé tẹlẹ ma baa tun ṣẹlẹ.
Bákan náà ni Bisoọọbu Joshua Oyinlola tun fi àsìkò náà ké sí Gómìnà Seyi Makinde láti ṣe gbogbo ohun to ba wa ni ìkápá rẹ lati mú kí ètò ẹkọ gbera sọ. O wa tun sàlàyé pé bí ọpọlọpọ se n sáré lati lo kàwé ní ilé ẹkọ gíga tí aladani ko fún orilẹ èdè yìí lórúko rere. O wa bẹ ìjọba apapọ lati mu agbega dé bá eto ẹkọ ni orílè èdè Nàìjíríà ko lè fi ẹgbẹ kẹgbẹ pẹlu awọn ile ẹkọ gíga ní oke òkun.
Lara awon to peju síbi ìsìn idupẹ náà ni: Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde; Akọwe Ijoba ipinle Òyó, Olubanwo Adeosun; Oloye Bolaji Ayorinde (SAN); Ọgbẹni Oladipo Olasope (SAN); Ọjọgbọn Femi Osofisan ati aya re (ti won ṣe ọmọ ijọ náà); Ọjọgbọn Elegbede, ati awọn ọjọgbọn ati olùkọ ilé ẹkọ gíga fasiti míràn.
Abiola Olowe
Ìbàdàn