Take a fresh look at your lifestyle.
Election

Adiro Ìdáná Tuntun Tí Ilẹ̀ Kenya Gbà Àmì Ẹyẹ $1.2M

0 124

Olùdásílẹ̀ Adiro ìdáná tuntun “Mukuru Clean” ní orílẹ̀-èdè Kenya Charlot Magayi, gbá ẹbùn owó mílíọ̀nù Kàn lé díẹ̀ dọla lọ́wọ́ Ọmọ Ọba Ilẹ̀ Gèésì William ní ìdíje “Earthshot Prize Award.”

Àwọn adiro Mukuru náà ní àgbà lérò pé yóò jẹ́ itẹwọgbà lọ́wọ́ àwọn Obìnrin ìlú Kenya àtí Áfíríkà lapapọ.

Ìwádìí fi hàn pé, bílíọ̀nù kàn dín làádọ́ta ènìyàn ní ìhà isalẹ aṣálẹ ni Áfíríkà “sub-Saharan Africa” ló gbéra lé lílo ìgi tàbi èédú fún ìdáná tí o sí ṣeéṣe kó lé ní bílíọ̀nù kàn ní ọdún 2050

Charlot Magayi, ọmọ ọdún mọkandinlọgbọn (29), bẹ̀rẹ iṣẹ́ àkànṣe náà ní ọdún 2017 ní Mukuru kwa Njenga.

“Èròngbà rẹ̀ ní pàtàkì ní pé yóò ṣé adinku àwọn tí wọ́n lò èpò òyìnbó, ìgi tàbí èédú fí dáná ni orílẹ̀-èdè náà.”

Adiro náà tún jẹ́ olówó pọọku tí ìyè rẹ̀ kojú dọla mẹwàá ($10) lọ.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.