Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀ Èdè Ukraine Fi Ìyà Jẹ Àwọn Adarí Ilé Ìjọsìn Moscow

0 106

Orílẹ̀ èdè Ukraine ti fún àwọn alàgbà ìjọ wẹ́wàá (10) ní ìjẹníyà látàrí fífura síwọn pẹ̀lú níní ìbásepọ̀ pẹ̀lú ilé ìjọsìn (Church) Moscow.

 

Ìgbésẹ̀ náà wáyé látàrí bí àwọn adarí ìjọ mẹwa náà se ń ṣe àtìlẹyìn fún orílẹ̀ èdè Russia. Adarí àjọ ẹ̀sọ́ aláàbò orílẹ̀ èdè Ukraine ni ó fi ẹ̀sùn kàn bẹ́ẹ̀.

 

Ìjẹníyà náà yóò wà fún ọdún márùn-ún, nígbà tí yóò gbé ẹsẹ̀ lé dúkìá àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn, tí wọn kò sì ní le è kó nǹkan jáde lọ sí orílẹ̀ èdè míràn, àtipé wọn kò ní ní ànfààní láti ní tàbí ra ilẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Ukraine.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.