Àjọ tí ó ń mójú tó ọkọ̀ ojú irin ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, The Nigeria Railway Corporation (NRC) ti fi léde wípé, ọkọ̀ ojú irin ti òpópónà Abuja si Kaduna yóò bẹ̀rẹ̀ isẹ́ padà ní ọjọ́ ajé, ọjọ́ kaàrún, osù kejìlá, ọdún 2022. (5th December, 2022)
Ìjọba àpapọ̀ pàsẹ ìgbésẹ̀ isẹ́ bíbẹ̀rẹ̀ náà láti ọwọ́ ẹka tí ó ń mójú tó ìgbòkè gbodò ìrìn àjò ọkọ̀, tí ósì fi àwọn àsìkò tí ọkọ̀ náà yóò máa rìn léde.
Wọ́n fi àrídájú hàn pé ààbò tí ó péye ti wà fún àwọn èrò ọkọ̀ náà àtipé kí olúkúlùkù tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin ìrìnàjò ọkọ̀ ojú irin náà kí wọ́n le è rí ànfààní ètò náà.
Leave a Reply