Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Niger Fún Emir Kagara Ní Ọ̀pá Àṣẹ

0 104

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger, ní ààrin gbìngbìn Arewa orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Abubakar Sanni Bello ti fún Emir Kagara ẹlẹ́ẹ̀kejì, Mallam Ahmed Garba Gunna Attahiru II ti ìlú Kagara, ìjọba ìbílẹ̀ Rafi ní ọ̀pá àṣẹ.

 

Níbi ayẹyẹ náà, gómìnà fi àrídájú hàn pé gbogbo àwọn tí ó sá kúrò ní ibùgbé wọn látàrí ìdààmú àwọn agbésùmọ̀mí yóò padá sí ibùgbé wọn ní àlàáfíà.

 

Gomina kí Emir àti alága ìjọba ìbílẹ̀ náà fún iṣẹ́ takun-takun wọn láti rí i dájú pé àlàáfíà jọba ní ìbílẹ̀ náà, ó sì gba àwọn aráìlú níyànjú láti fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Emir fún àkóso tí o yanjú.

 

Emir Kagara nínú ọ̀rọ̀ rẹ se àdéhùn láti jẹ́ adarí tí ó dára, ó sì kí Gómìnà fún ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i Emir tuntun.

Leave A Reply

Your email address will not be published.