Take a fresh look at your lifestyle.

Àrọwà Ti Wá Láti Sọ́ra Fún Àwọn Oníjìbìtì Lórí ọ̀rọ̀ Ìdókoòwò

0 157

Àjọ tí ìjọba àpapọ̀ gbèrò láti dá sílẹ̀ fún ìdókoòwò ti ké gbàjarè, ó sì se ìkìlọ̀ láti máse ṣe àmúlò ìkànnì kan lórí ayélujára, National start Up Investment Fund-NISF. Ọ̀nà náà jẹ́ ìgbésẹ̀ jìbìtì láti ja àwọn ènìyàn lólè, pẹ̀lú gbígba ìròyìn nípa wọn láti ló ó fún ìwà ọ̀daràn míràn.

 

Ó sàlàyé síwájú pé, ìjọba àpapọ̀, ilé ìfowópamọ́ fún ilé iṣẹ́ ( Bank of industry), Ilé ìfowópamọ́ fún ìdàgbàsókè ilẹ̀ adúláwọ̀ (African Development Bank) kò fi ọwọ́ sí ètò náà rárá.

 

Ìrètí wà pé ètò ìjọba àpapọ̀ láti pèsè owó fún ìdókoòwò yóò gbéra sọ láìpẹ́ àtipé wọn yóò fi ọ̀rọ̀ náà léde kété tí ètò náà bá ti bẹ̀rẹ̀. Wọ́n rọ mùtúmùwà láti sọ́ra fún àwọn oníjìbìtì ẹ̀dá ki wọn ma baà pàdánù dúkìá wọn.

Leave A Reply

Your email address will not be published.