Take a fresh look at your lifestyle.

Argentina Gbo Ewúro Sí Ausrtalia Lójú Pẹ̀lú Àmì Ayò Méjì Sí Òdo

0 220

Gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù ọmọ Argentina, Lionel Messi fa akọ yọ nígbà tí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà kojú akẹgbẹ́ rẹ láti orílẹ̀ èdè Australia níbi bọ́ọ̀lù ife ẹ̀yẹ àgbáyé. Bí o tìlẹ́ jé pé Australia náà jẹ àmì ayò kan, sùgbọ́n kíkùnà rẹ̀ láti jáwé olúborí ti fún ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Argentina ní ànfààní láti kojú òsùwọ̀n fún kíkojú akẹgbẹ́ rẹ̀ ní orílẹ̀ èdè Netherlands ní ọjọ́ iwájú.

 

Atamọ́tàsé agbábọ́ọ̀lù ọmọ Argentina, Lionel Messi fa akọ yọ tí ó sì gba bọ́ọlu sínu àwọ̀n lẹ́yìn ìsẹ́jú máàrúndílógójì tí eré ìdárayá náà bẹ̀rẹ̀ tí ariwo sì ta ní pápá àdárayá Ahmad Bin Ali.

 

Lẹ́yìn ìséjú mẹ́tàdílọ́gọ́ta ni Julian alvavez tí ó jẹ́ ọmọ agbábọ́ọ̀lù Argentina jẹ àmì ayò kejì, èyí ló mú kí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà jáwé olúborí.

 

Àmì ayò tí Messi jẹ ni ó jẹ́ ẹlẹ́ẹ̀kẹta irú rẹ níbi ife ẹ̀yẹ àgbáyé tí ó ń lọ lọ́wọ́ ní orílẹ̀ èdè Qatar, tí ó sì jẹ àmì ayò ẹlẹ́ẹ̀kẹkẹ̀sán tí ó ti jẹ́ ni àgbáyé.

Leave A Reply

Your email address will not be published.