Take a fresh look at your lifestyle.

Àfẹnukò Ti Wà Lórí Ọ̀rọ̀ Àlàáfíà Láàrin Orílẹ̀ Èdè Colombia Àti Àwọn Ọmọ Ogun Ọlọ̀tẹ̀

0 126

Ààrẹ orílẹ̀ èdè Colombia, Gustaro Petro sọ wípé ọ̀rọ̀ àlàáfíà tí ó ń lọ láàrin ìjọba orílẹ̀ èdè náà àti àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀, The Left wing National Liberation Army (ELM) ti so èso rere.

 

Ààrẹ Petro sọ wípé àfenukò ti wà láàrin ikọ̀ méjéèjì láti ri dájú pé ààbò tí ó péye wà fún àwọn ènìyàn tí rògbòdìyàn lé kúrò ní àgbègbè wọn àtipé wọ́n gbọdọ̀ padà sí ibùgbé wọn ní àlàáfíà. Ó fi ọ̀rọ̀ náà léde nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí Antioquia.

 

Ó tẹ̀ síwájú pé, ikọ̀ méjéèjì kò ì tí ì ki idà bọ àkọ̀ nígbà tí ogun sì ń tẹ̀ síwájú, sùgbọ́n láìpẹ́ òpin yóò dé bá wàhálà náà.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.