Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Fi Ìpìlẹ̀ Ọ́ọ́fìsì Àpapọ̀ ECOWAS Lélẹ̀ Ní Ìlú Abuja

0 109

Ààrẹ Buhari ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìpìlẹ̀  ọ́ọ́fìsì àpapọ̀ àjọ ECOWAS  ní ìlú Abuja, olú ìlú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

 

Ààrẹ, ẹni tí ààrẹ  Umaro Embalo ti orílẹ̀ èdè Guinea Bussau ati ààrẹ Julius Mada Bio ti orílẹ̀ èdè Sierra Leone kọwọrin pẹ̀lú rẹ̀ sọ wipe, píparí gbọ̀ngàn náà yóò mú ìsọ̀kan ba àjọ ECOWAS.

 

Ìjọba orílẹ̀ èdè China ni ó fi gbọ̀ngàn náà ta àjọ ECOWAS lọ́rẹ, ti wọn yóò sì máa pè é ní “Àmúyẹ ìwọ̀ oòrùn Africa” ( Eye of West Africa). Ìrètí wà pé isé náà yóò parí ní osù kejì ọdún 2025 ( February, 2025).

Leave A Reply

Your email address will not be published.