Take a fresh look at your lifestyle.

Flying Eagles Lu City FC Abuja Bí Ẹni Lu Aṣọ Ofi Ni Ayo Márùn ún Sí Odo(5-0) Tí Àyúbà Sì Dá Bírà.

0 115

 

Àyúbà Francis àti Abdulraman agbábọ́ọ̀lù ẹnìkejì rẹ̀ jọ se bẹbẹ lórí pápá nìgbà tí ikọ̀ wọn fi ìyà tó gbúpọn je alátakò wọn láti ìbẹ̀rẹ̀ eré títí dópin.

Ní nkàn bí ìsẹ́jú mẹ́wàá àkọ́kọ́, Flying Eagles ti ju èkíní síí nípasẹ̀ wòmí kí n gba ṣí ọ(Penalty). Èkejì tún wọlé láti ẹsẹ̀ agbábọ́ọ̀lù náà ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rà wá láti Nasarawa United, Ayuba Francis nígbàtí èkejì rẹ̀ Alex Nwoya gbá bọ́ọ̀lù náà síi.

Orí ló tún kó Asọ́lé City FC yọ kí ìkẹta má tún wọlé láti ọ̀dò ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù náà lẹ́yìn ìsẹ́jú méjì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà ọ̀kan wọlé.

Àyúbà Francis bẹ̀rẹ̀ bọ́ọ̀lù gbígbá rẹ̀ pẹ̀lú Iko Allah Boys ni Kaduna kó tó lọ se àgbàse ní sáà tó kọjá ní FC one rocket ni ilu Uyo. Ó jẹ́ agbábọ́ọ̀lù tó dára fún NPFL ati Orílè-èdè yìí.

Flying Eagles paí ìdíje náà pẹ̀lú ayò márùn ùn sí òdo. Nàìjíríà ti sọ ayo mẹ́wàá sí àwọ̀n báyìí tí bóòlù kankan kò sì tí wọlé Nàìjíríà nínú ìdíje méjì. Ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ tó dára fún agbábọ́ọ̀lù ilẹ wa, pàápàá tún ìmúrasílẹ̀ AFCON ọdún tó n bọ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.