Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Ebonyi: Alága Ẹgbẹ́ Òṣèlú APC Bú Ẹnu Àtẹ Lú Iná Tó Ṣẹlẹ̀ Ní Ọ́fíìsì Àjọ INEC

0 314

Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Ebonyi, Ọgbẹni Stanley Okoro Emegha tí bú ẹnu àtẹ lú dídá’ná sún ilé-iṣẹ́ élétó ìdìbò (Independent National Electoral Commission INEC) tó wà ní Izzi, ìjọba ìbílẹ̀ Iboko, ní ìpínlẹ̀ Ebonyi.

Okoro Emegha sọ fún àwọn oníròyìn ní Abakaliki Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ náà pé àwọn ẹlẹṣọ ààbò nì Ìpínlẹ̀ náà tí bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti fí ojú àwọn aṣebi hàn.

Alága APC ní ìpínlẹ̀ náà, tó tún jẹ́ Olùdámọ̀ràn Ààbò fún ìjọba Ìpínlẹ̀ Ebonyi, fí kún pé òfin gbọ́dọ̀ mú àwọn tó ṣẹ iṣẹ ibí ní ìbámu pẹ̀lú òfin. A kò lé jẹ́ kí àwọn òní jagidijagan tí àwọn ẹgbẹ́ alatako tí kò tíì rí ohunkóhun tó dára nínú ìṣàkóso tó ń lọ lọwọlọwọ ń ló látí tẹ̀síwájú látí pá àwọn nkán run fún wa”, o fi kun.

O pé àwọn ènìyàn Ebonyi láti ṣé ìrànlọ́wọ́ ní ẹ̀kà ààbò ní Ìpínlẹ̀ náà nípa títà àwọn agbofinro ní olobo lórí òun-kó-ùn tí wọ́n bá fura sí ní agbègbè wọ́n.

Ní idakeji ẹwẹ, Alága tí ẹgbẹ́ òṣèlú Young Progressive Party YPP, Ọgbẹni Stanley Oyibe sọ pé YPP gẹ́gẹ́ bíí ọ̀kan nínù áwọn ẹgbẹ́ alatako ní Ìpínlẹ̀ náà jìnà sí ẹsùn náà.

O tẹnumọ pé ẹnikẹni tó bá ní ọwọ́ nínù ìṣẹlẹ iná tí ilé iṣẹ́ àjọ élétó Ìdìbò INEC, òfin ní kí wọ́n fí gbé é.
Sibẹsibẹ, Oyibe ṣàlàyé bí ìṣẹlẹ náà ṣé lé kọ̀ di ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ náà níbí ètò ìdìbò gbogbogbòò tó ń bọ̀ lọ́nà.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button