Take a fresh look at your lifestyle.

Ayẹyẹ Èrè Ìdárayá Tí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà: Ìpínlẹ̀ Niger Ṣé Ìlérí Fún Àwọn Aṣojú Rẹ̀

0 177

Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger tí ṣé ìlérí fún àwọn eléré ìdárayá tí o ń ṣoju ìpínlẹ̀ náà ní tí ọdún kọkanlelogun iru rẹ̀ (National Sports Festival NSF), ti yóò wáyé ní Asaba, Olú-ìlú ìpínlẹ̀ Delta ní apá gusu tí Orílẹ̀-èdè yìí ní ẹsan nlá wà fún èyíkéyìí ami-eye tí aṣojú àwọn bá gbà.

Kọmisana èrè ìdárayá àtí Ìdàgbàsókè àwọn ọdọ ní ìpínlẹ̀ náà, MalamYusuf Suleiman ló sọ ọrọ yìí lásìkò tó ń bá àwọn eléré ìdárayá náà s’ọrọ ní ìparí ìbùdó kàn ti ilé-iṣẹ́ náà ṣètò.

Suleiman sọ pé gbogbo àwọn ìlérí tí wọ́n ṣé fún àwọn eléré ìdárayá náà ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpagọ ní àwọn tí ṣé pẹ̀lú sisanwo ajẹmọnu wọ́n ati àwọn òhun mìíràn tí béèrè fún.

“Emi kii yoo ṣé ìlérí k’ọkan fún ẹnikẹ́ni ṣùgbọ́n mo ní ìdánilójú pé wọ́n yóò sàn ẹsan fún èyíkéyìí ami-eye tí o bá gbà fún ìpínlẹ̀ náà. Nitorina, Mó rọ yín látí ṣé Daradara fún ara rẹ àti fún ìpínlẹ̀ Niger.”

Mal Yusuf Suleiman tún sọ pé gbogbo òhun tí ìjọba ìpínlẹ̀ náà ṣètò ní láti jẹ́ kí inú àwọn eléré Ìdárayá dùn ní Asaba lásìkò èrè náà ìdí níyii ti a fi sàn ìdajì nínú gbogbo owó ajẹmọnu yín àti àwọn ohun mìíràn tí ìdajì tó kù yóò di sisan ki èrè ìdárayá náà tó parí.

Yunusa Taminu, Akọ̀wé àgbà ilé-iṣẹ́ ètò èrè ìdárayá àti ìdàgbàsókè àwọn ọdọ ní ìpínlẹ̀ náà pé “wọ́n yóò mọ rírí èyíkéyìí eléré ìdárayá tàbí ẹgbẹ́ tó bá gbà àmì-ẹyẹ wálé.”

Nígbà tó n fèsì lórúkọ àwọn eléré ìdárayá, Femi Tunji, ọmọ ẹgbẹ́ agbabọọlu ọlọwọ, dúpẹ lọ́wọ́ Kọmisana àti ẹgbẹ́ alàkóso rẹ̀ fún bí wọ́n ṣé mú ìlérí wọ́n ṣẹ lásìkò àti ìparí ìbùdó náà. Wọ́n sì ṣé ìlérí pé àwọn yóò fakọyọ ní Asaba pẹlú àmì-ẹyẹ lorisirisi fún náà.
Àwọn eléré ìdárayá mẹrindinlọgọrun ní yóò ṣé ṣe aṣojú Ìpínlẹ̀ náà ní ajọdun èrè ìdárayá tí orílẹ̀-èdè yíì tí nlọ ní Delta.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.