Take a fresh look at your lifestyle.

Orílè-èdè Cameroon Gbá Ọ̀mìn Pẹ̀lú Orílè-èdè Serbia.

0 124

Orílè-èdè Cameroon gbá ayò ọ̀mìn mẹ́ta sí mẹ́ta (3-3) ni ìsọ̀rí G pẹ̀lú orílè-èdè Serbia. nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé 2022 tó ń lọ lọ́wọ́ ní pápá ìseré Al Janoub ní ìlú Al Wakrah, orílè-èdè Qatar.


Egbé agbábọ́ọ̀lù Indomitable Lions ti orile-ede Cameroon lo kókó dá àwọn lu ni iṣẹju kọkandinlọ́gbọ̀n láti ese Jean-Charles ti orile-ede Serbia sì fi meji dáa padà ki abala akoko to pari.
.yi

Bi abala Kejì tun ti bere ni orilẹ ede Serbia tun dín dundu iya bóòlù ayo meji sí fún Orílè-èdè Cameroon lati ese agbábọ́ọ̀lù Strahinja Pavlovic ati Sergej Milinkovic-Savic ti gbogbo re lapapo fi je meta sí odo (3-1) to wà fi orílè èdè Cameroon sinu ẹrú.

Ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù ọmọ orílè èdè Cameroon, Vincent Aboubakar ni wón pe ko wa gba wón la láti ibi to joko sí. Rírọ́po agbábọ́ọ̀lù kan lori papa sí so eso rere nítorí kété tó wolè ló mi àwọ̀n titi ní iṣẹju metalelogọ́ta to mú kí inú àwọn èrò iworan dun diẹ.

Agbábọ́ọ̀lù fún Orílè-èdè Cameroon, Choupo-Moting lo so ikẹ̀ta síi tó fi jẹ́ mẹta sí mẹta (3-3) nigba ti enikeji rẹ gba sí láti ràn lọ́wọ́ ti àwọn agbábọ́ọ̀lù àti àwọn olólùfẹ́ wọn sí fò f’áyọ̀.

Orílè-èdè méjèèjì nílò láti borí Ifesewonse wọn tó ń bọ ti wọn bá fẹ́ peregede sí ipele ẹlẹ́ni merindinlogun. Amin kọọkan ní orilẹ ede mejeeji sí ni.

Cameroon yóò kojú Brazil ní ọjó ẹtì,
Serbia ní tirẹ̀ yóò koju Switzerland. Wọ́n ní láti borí láti leè tẹ̀ síwájú.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.