Take a fresh look at your lifestyle.

Ona TI Abaji,Alhaji Adamu Baba Yunusa sayẹyẹ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n lórí ìtẹ́,ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá,ìlú Àbújá sàjọyọ́ pẹ̀lú rẹ̀

0 2,245

Ona of Abaji , to tun jẹ alaga igbimọ awọn lọba-lọba niluu Abuj,FCT ,His Royal Majesty (HRM) Alhaji Adamu Baba Yunusa sayẹyẹ sayẹyẹ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n (25 years)lórí ìtẹ́, ni eyi ti gbogbo toni;e talejo wa sibi ayẹyẹ naa to waye ni Abaji , niluu Abuja to jẹ olu-ilu orilẹ ede Naijiria.

Alhaji Yunusa,ni yoo jẹ ọba kẹrindinlogun to jẹ Ona ti Abaji, ti o gba ọ̀pá asẹ gẹgẹ bi adari  ọba ni  ọjọ́ kejilelogun osu Kẹjọ ,ọdun 1997 gẹgẹ bi  Ona tiAbaji ati alaga gbogbo lọba*lọba ni ilu Abuja.

Lasiko ayẹyẹ ọhun,  Alhaji Yunusa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aabo rẹ lati wa lórílẹ̀ alàyè ati ní alaafia lati lee maa sakoso awọn eniyan rẹ̀.

O tun dupẹ lọwọ awọn igbimọ lọba-lọba fun ati lẹyin wọn lati lee jẹ ki alaafia ati isọkan jọba ni ilu Abuja.Ọba Yunusa tundupẹ lọwọ awọn ẹgbẹ Yoruba ati awọn ẹya miran fun gudu-gudu meje yaya mẹfa ti wọn n se niluu Abuja.

Aarẹ ẹgbẹ awọn Yorùbá lorilẹ ede Naijiria, Alhaji AbdulHakeem Mosebolatan naa sapejuwe Ọna Abajai gẹgẹ bi  alaanu eniyan ati ẹni to tun nifẹẹ awọn ara ilu rẹ ati ẹya miran, ti kii n se ẹni to maa n se ojụ-sàájú. Aaarẹ tun wa gbadura pe ki Ọlọ́run tubọ fi ẹmi gígùn ati alaafia fún ọba naa lori ìtẹ́.

lara awọn to tun péjú pẹ́sẹ̀ asofin ilu Abuja, Philips Tanimu Aduda, alaga ẹgbẹ ọmọ Yoruba ti ijọba ibilẹ Bwari to tun jẹ adari awọn ẹgbẹ Vigilante orilẹ ede Naijiria , Ọmọjuni Mattew , awọn ọba Yorùbá ilu Abuja ati gbogbo  ẹgbẹ ọmọ Yoruba to n gbe ni ilu Abuja, FCT.

Leave A Reply

Your email address will not be published.