Take a fresh look at your lifestyle.

Olórí Òṣìṣẹ́ Ààrẹ Gbà Oyè Ìbílẹ̀ Tintun Ní Nasarawa

0 641

Oyè ìbílẹ̀ tuntun gẹ́gẹ́bí aláàbò Ọba – “Zanna Yawu Dima ti Laffan Bare -Bari,” ní a tí fún Olórí Òṣìṣẹ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, ní Ààfin Emir tí Lafia, Ìpínlẹ̀ Nasarawa, Àríwá aaringbungbun Nàìjíríà.

Emir tí Lafia, Sidi Bage sọ pé oyè náà ní wọ́n fí fún Olórí Òṣìṣẹ́ látàrí bí o ṣé dúró déédé lórí iṣẹ́ ìlú.

Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, ẹní tó ṣé àbẹwò ọlọjọ méjì sí ìpínlẹ̀ Nassarawa, nígbà tó gbà oyè náà, ṣé ìlérí láti tèsíwájú àti sá gbogbo ipá rẹ̀ fún ẹtọ ọmọnìyàn àti àlàáfíà àwọn ènìyàn Lafia Emirate àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀.

Ó tún rọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbà àlàáfía láàyè àtí ìsọkan onírúurú fún àṣeyọrí àti Ìdàgbàsókè orílẹ-èdè yìí.

Gẹ́gẹ́ bí o tí sọ, àwọn Olùdarí gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìsọkan àti ifarada láàrín gbogbo ẹyà ní orílẹ̀-èdè náà.

Nibayii, olórí àwọn òṣìṣẹ́ to tí fí ìgbà kàn rí ṣé àbẹwò sí ilé iṣé oko àti òhun èlò (AMEDI) Lafia, sọ pé kíkọ ilé iṣé àgbẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè yìí jẹ́ àmì fún ìdàgbàsókè iṣẹ ọ̀gbìn káàkiri orílẹ̀-èdè yíì.

O tún ṣé ìdánilójú lórí iṣẹ́ àkànṣe náà, èyítí National Agency for Science and Engineering Infrastructure (NASENI) kọ yóò jẹ́ kí orílẹ-èdè Nàìjíríà le ṣé ìdàgbàsókè tintun ní ọjà ọ̀gbìn.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.