Take a fresh look at your lifestyle.

Orúkọ Àwọn Àgbàbọ́ọ̀lù Tó Máa Ṣojú Nàìjíríà Nínú Bọ́ọ̀lù Ọlọrẹ Sọrẹ Pẹ̀lú Portugal Yóò Jáde Ní Ọjọ́ Àjé

0 244

Àjọ Bọ́ọ̀lù afesegba lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà (NFF), sọ nínú ọ̀rọ̀ wọ́n pé olùkọní Super Eagles, Jose Peseiro yóò ṣé àfihàn orúkọ àwọn àgbàbọ́ọ̀lu mẹ́tàlélogún (23) ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ keje, oṣù kọkànlá (Mon November 7th) fún Ifẹsẹwọnsẹ Ọlọrẹ sí ọrẹ láàrín orílẹ̀-èdè Portugal àti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Akọ̀wé Àgbà NFF, Dókítà Mohammed Sanusi sọ nínú àtẹ̀jáde kàn pé Peseiro tí ń ṣé iṣẹ rẹ̀ laísì ìdààmú, o tọka síi pé orúkọ gbogbo àwọn àgbàbọ́ọ̀lù ti yóò kópa nínú Ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹ s’ọrẹ náà tí wá ní sẹ́pẹ́.

“A ní ìdíje ọlọrẹ sí ọrẹ kàn pẹlú Ìlú Portugal tí yóò wáyé ní Lisbon ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹtadinlogun Oṣù kọkànlá ọdún yìí (17/11/2022), Ọgbẹni Peseiro tí ṣé àkójọpọ̀ orúkọ àwọn àgbàbọ́ọ̀lu tó máa kópa àti pé o ń dúró dé àwọn Ifẹsẹwọnsẹ òpin ọsẹ yii kó tó fí orúkọ àgbàbọ́ọ̀lù mẹtalelogun (23) náà sílẹ̀.”

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button