Àjọ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù lápapọ̀, NFF, ti gbà pé òun jẹ olùkọ́ni Super Eagle Jose Peseiro ní owó osù.
Àwọn akọ̀ròyìn ti sọ ní ọ̀sẹ̀ yìí pé wọ́n jẹ Pọtugí ní gbèsè owó oṣù mẹ́fà.
Peseiro,tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlé-lọ́gọ́ta, tí ó gbaṣẹ́ ní oṣù karùn ún, fọwọ́ sí àdéhùn iṣẹ́-ṣíṣe pẹ̀lú Nàìjíríà fún ọdún kan pẹ̀lú owó osù tí ó jẹ́ ààdọ́rin ẹgbẹ̀rún Dọ́là.
Akọ̀wé Gbogbogbòò NFF, Mohammed Sanusi, sọ pé àjọ náà ń ṣiṣẹ́ lórí sísan gbèsè náà fún olùkọ́ni Pọtugí.