Ààrẹ Nàìjíríà, Mùhámmádù Bùhárí ti yan Mínísítà àyíká, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Abdullahi láti ṣojú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adarí aṣojú Nàìjíríà sí àpèjọ àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé.
Àpèjọ lórí ìyípadà ojú-ọjọ́ náà yóò wáyé ní Sharm El Sheikh,ní Egypt, láti ọjọ́ kẹfà sí ọjọ́ kejìdín-lógún,oṣù Kọkànlá,ọdún 2022.
Abdullahi yóò ṣojú Ààrẹ ní ìpele gíga tí yóò sì tún ṣe ìjábọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà níbi ìjíròrò Cop27, yóò tún sẹ ìpàdé pẹ̀lú ẹgbẹ́ lórí ètò ìyípadà iná Nàìjíríà láàrin àwọn ìpinnu mìíràn.