Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ̀ Ògùn ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ìdàgbàsókè ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ́nù Dọ́là SAPZ

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 204

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn ti ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìdàgbàsókè ètò iṣé àdàṣe pàtàkì ilé-iṣẹ́ ìpèsè àti iṣẹ́- ọ̀gbìn Ìlú oní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ́nù Dọ́là (SAPZ),gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ìpínlẹ̀ mẹ́jọ tí wọ́n mú fún alákòóso àkọ́kọ́ ètò náà ní Nàìjíríà.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, Dàpọ̀ Abíọ́dún, níbi ayẹyẹ tí ó wáyé ní pápákọ̀ òfurufú tí wọ́n ti ń di àwọn ẹrù oun ọ̀gbìn,ní Ìliṣàn-Rẹ́mọ, sọ pé ilé-iṣé ìpèsè àti iṣé ọ̀gbìn ti agbègbè Ògùn,ti abala àkọ́kọ́ rẹ̀ tó tó  iye owó irínwó mílíọ́nù Dọ́là,yóò parí ní nǹkan bíi oṣù méjìdín-lógún.

Gómìnà náà sọ pé iṣẹ́-àdàṣe náà jẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Arise Integrated Industrial Platform àti ìjọba ìpínlẹ̀ ògùn. Ó sọ̀rọ̀ síwájú pé ilé-iṣẹ́ pàtàkì fún ìpèsè ètò ọ̀gbìn àti àwọn nǹkan tó jọ mọ́ọ,alákọ́kọ́ọ́ irú ẹ̀ ní orílẹ̀ -èdè,yóò pèsè iṣẹ́ tí ó ju ogún ẹgbẹ̀rún lọ àti arísìkí ènìyàn kọ̀ọ̀kan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.