Ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti rọ àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Rivers, gúsù Nàìjíríà láti kópa nínú ìgbanisíṣẹ́ lọ́pọ̀ yanturu sí 84 Rular Recruit Intake,RRI,tí ó ń lọ Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.
Olùdarí,ètò òṣìṣẹ́ ti Ẹ̀ka ìṣàkóso olú ilé-iṣẹ́, ajagun Ibrahim Jallo,sọ eléyìí nígbà tí ó ṣe adarí ikọ̀ tí ó ṣe àbẹ̀wò sí akọ̀wé ìjọba ìpínlẹ̀ Rivers, Mr Tammy Danagogo.
Ajagun Jallo ṣàlàyé pé ìbèwò náà jẹ́ ìgbésẹ̀ lẹ́yìn àwọn ìlànà àfọ̀kànsí ọ̀gá àgbà fún àwọn ọmọ ogun, COAS,ajagun Farouk Yahaya lóríi pé àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Rivers kò tíì pé nínú ìpín tiwọn fún ìgbani sínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Nàìjíríà.
Ó sọ fún Danagogo pé ìgbani síṣẹ́ẹ 84 Regular Recruit Intake tí ń lọ lọ́wọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ní oṣù kẹwàá tí yóò sì parí ní ọjọ́ kejì, Oṣù kejìlá 2022.