Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Aṣòfin Èkó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí ìṣúná owó ọdún 2021 àwọn ẹ̀ka ilé-iṣẹ́ ìjọba kan

0 90

Ile Igbimọ Aṣofin Ipinlẹ Eko bẹrẹ iṣẹ iṣewadii iṣuna owo ọlọdọọdun ti wọn maa n ṣe lori akọsilẹ Ile-iṣẹ Ayẹwe-owo-wo Agba Ipinlẹ Eko ati iṣuna owo awọn ile-iṣẹ ijọba, ẹka ile-iṣẹ ijọba ati awọn ajọ ile-iṣẹ ijọba ni Ipinlẹ Eko. Eto iṣuna owo ọdun 202 ni wọn fẹ ṣe iwadii rẹ lati mọ bi wọn ṣe na owo ti wọn yà sọtọ fun wọn fun ọdun naa ati lati mọ boya wọn tẹle ofin ati ilana to yẹ ninu inawo wọn naa.

Alaga Igbimọ Aṣamojuto Apo-owo Ijoba Ipinlẹ ninu Ile Aṣofin naa, Aṣofin Nurudeen Saka-Ṣolaja lo sọrọ yii di mimọ ninu ọrọ ikini-kaabọ rẹ nibi ipade iṣewadii naa, eleyii ti wọn bẹrẹ ni ỌjọRu, ọjọ keji oṣu kọkanla, ọdun 2022 ni gbagede Ile Aṣofin naa ni Ikẹja.

Igbimọ Aṣamojuto Apo-owo Ijoba Ipinlẹ ninu Ile Aṣofin yii ni wọn ṣagbekalẹ labala karundinlaadoje ati ikọkandinlaadoje ninu iwe-ofin orilẹ-ede Naijiria ti ọdun 1999 pẹlu atunṣe rẹ.

Igbimọ naa ṣe pataki gẹgẹ bi ohun elo Ile Igbimọ Aṣofin kan lati maa mojuto eto iṣuna-owo ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ. Ofin naa fun igbimọ naa lagbara lati pe ẹnikẹni lorilẹ-ede Naijiria lati wa sọ tẹnu rẹ ohun to mọ nipa iṣuna owo kan.

Aṣofin Saka-Solaja (to n ṣoju ẹkun idibo Ikorodu Keji) ṣalaye pe ojuṣe iṣewadii iṣuna owo yii ki i ṣe lati fi wa ipalara fun ẹnikan tabi lati fi ṣe ẹtaanu. O ni, iwadii yii nii ṣe pẹlu awon ile-iṣẹ ijọba tabi ẹka ile-iṣẹ ijọba tọrọ kan ni titẹle abajade ile-iṣẹ Ayẹwe-owo-wo Agba ipinlẹ yii lori wọn, eyi ti abajade idahun si awọn ibeere bẹẹ le mu igberu ba iṣakoso ipinlẹ yii siwaju. O ni, “iṣẹ iwadii yii yoo le jẹ ka mọ ododo ipele ti iṣuna owo de ni awọn ẹka ọrọ-aje gbogbo ni ipinlẹ yii”.

“Ati pe iṣẹ iwadii yii yoo nii ṣe pẹlu ẹrọ ti wọn n lo lati fi ṣe iṣuwona wọn ati ilana ti awọn ile-iṣẹ ijọba ati ẹka ile-iṣẹ ijọba yii fi n mojuto inawo wọn. Igbẹkẹle awọn ara ilu pọ lori awọn ẹka ile-iṣẹ yii gẹgẹ bi eyi ti awọn ipinlẹ yooku n ri fi ṣe awokọṣe fun fifi ododo ṣiṣẹ wọn”.

Aṣofin Saka-Ṣolaja fi da awọn ile-iṣẹ naa loju pe gbogbo abajade iwadii naa lawọn yoo ṣe ni finnifinni laifigba kan bọkan ninu, ti awọn yoo si fi ṣowọ si Ile Aṣofin naa lati pinnu le wọn lori gẹgẹ bo ṣe yẹ.

O ni, gẹgẹ bi erongba Oludari Ile, Aṣofin Mudashiru Ọbasa, gbogbo ọna lati mu igbe aye rọrun fun awọn ara ilu lo ṣe pataki ninu iṣẹ aṣofin. Ati pe, abajade iwadii yii yoo tubọ mu igberu ba imojuto awọn ọrọ-aje ipinlẹ yii.

Leave A Reply

Your email address will not be published.