Take a fresh look at your lifestyle.

Usyk: Fury Nìkan Ní Mó N’ìfẹ Sí Láti Bá Já

0 90

Oleksandr Usyk ti jẹ́ kó yé wá pé ọmọ Biritiko Tyson Fury Nìkan ní òún nife sí láti bá ja nitori wípé òún fẹ́ gbà adé àgbáyé to gbà lọdún to kọjá lọ́wọ́ rẹ̀.

Ọmọ ọdún márùndínlógójì tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ukraine náà ní adé àwọn afẹṣẹkan àgbáyé WBA, WBO, IBF àti IBO wà lọ́wọ́ rẹ̀, èyí tó gbà nígbà tó ṣẹ́gun Anthony Joshua nínú oṣù kẹjọ. Ṣùgbọ́n, o tún fẹ́ gbà adé WBC Fury láti ṣé àkójọpọ̀ àwọn adé náà sì ọwọ́ rẹ̀.

Fury, ọmọ ọdún mẹrinlelọgọta ni yóò kojú Derek Chisora ​​fún ìgbà kẹta ní ọjọ́ kẹta Oṣù Kejìlá, lẹyìn tó tí lu ní ẹẹmeji ọtọọtọ ní ọdún 2011 àti 2014.

Ó sọ pé ati pàápàá òun ò fẹ́ dojú kọ ẹnikẹ́ni títí tóun yóò fí gbà ìgbànú Fury si ọwọ́ òun, tó sì dábàá pé eré náà yóò wáyé ní pápá ìṣeré Olimpiyskiy ní Kyiv.

O tún fi kún pé: “Ṣùgbọ́n kìí ṣe emi ní o yan ibí iṣere náà, nítorí náà mo rò pé ní àkókò yìí Saudi Arabia ní yóò jẹ.”

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.