Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Nàìjíríà (Flamingo) gba ipò kẹta mọ́ Germany lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n gbo omi ewúro sí wọn lójú nínú ìdíje U-17 ife àgbáyé 

0 140

Ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù obìnrin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà U-17, Flamingos fi àgbà han ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù Germany pẹ̀lú àmì ayò pẹnátì mẹ́ta sí méjì lẹ́yìn tí wọ́n jọ fakàngbọ̀n lóri pápá pẹ̀lú àmì ayò mẹ́ta-mẹ́ta, èyí tó mú wọn gba ipò kẹta nínú ìdíje U-17 ife àgbáyé ní orílẹ̀-èdè India ní Ọjọ́ àìkú.

Àwọn Flamingos ló kọ́kọ́ mi àwọ̀n mẹta, eyi to ti fi ọkàn wọn balẹ̀ pé àwọn ti gbégbá orókè, àwọn tó sì mi àwọ̀n ni Opeyemi Ajakaye, Amina Bello àti Etim Eddidiong, ó yani lẹ́nu púpọ̀ nígbà tí ẹgbẹ́ agbabọọlu Germany dìde tìbínú tìbínú tí wọ́n sì dá àmì ayò mẹta náà padà fún ẹgbẹ́ agbabọọlu Flamingos ní ẹ̀yìnọrẹ̀yìn.

Gọ́ọ̀lù ẹgbẹ́ agbabọọlu Germany kọ̀ọ̀kan jáde láti ọ̀dọ Jella Velt, Paulina Bartz àti Loreen Bender tó fi idán gbá bọ́ọ̀lù wọ inú àwọ̀n. Oun tó mú wọn dé pẹnátì nìyẹn ṣùgbọ̀n kágbà wípé Ọlọ́run wà lẹ́yìn àwọn ẹgbẹ́ agbábọ̀ọ̀lù ọmọbìrin Nàìjíríà torípé bí ìjì ṣe jà tó, wọ́n padà ṣẹ́gun ìjì náà.

 

ỌLÁYINKÁ AKÍNTỌ́LÁ.

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.