Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Gbégbá Orókè Nínú Eré Ìdárayá Ní Àgbáye

0 111

Ọdún 2022 jẹ́ ọdún málegbàgbé nínú ìtàn eré ìdárayá ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, nígbà tí àwọn olùkópa rẹ̀ jáwé olúborí ní àgbáyé, eléyìí tí ó wáyé ní Eugene, Oregon, United State. Àti eré ìdárayá common wealth ní Birmingham, England, fi dájú pé, Nàìjíríà làmì-laaka nínú eré ìdárayá.

 

Tobi Amusan borí nínú ìdíje eré sísá oní ọgọ́run-ún mítà, tí ó  sì parí rẹ ní ìsẹ́jú àáyá méjìlá ó lé díẹ̀ (12.1 sec.) ó sì gba àmìn ẹ̀yẹ góòlù. Ẹnìkejì rẹ̀ Ese Brume fo mìtà méje ó lé díẹ̀  (7.7m) níbi agùnfò (long jump) tí ó sí gbà àmìn ẹ̀yẹ fàdákà (silver).

 

Gbogbo àseyọrí wọ̀nyí wá sí ìmúsẹ pẹ̀lu ìrànlọ́wọ́ owó láti ọwọ́ ìjọba Nàìjíríà, àjọ aládáni àti àwọn ọmọ Nàìjíríà. Ó dájú pé pẹ̀lú ìgbìnjànjú lórí eré ìdárayá, dídùn ni ọsàn yóò so fún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nínú eré ìdárayá.

Leave A Reply

Your email address will not be published.