Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti rán àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ó wà ní orílè-èdè South Korea létí pé “aṣojú Nàìjíríà,”ni wọ́n jẹ́ àti pé ó yẹ kí wọn gbìyànjú láti ṣe ìgbélárugẹ orílẹ̀-èdè látara àwọn iṣé wọn,ìṣesí wọn , ìhùwàsí wọn, àti ìjọ́mọnìyàn wọn lápapọ̀.
Ààrẹ ṣàlàyé èyí ní Seoul ní Ọjọ́bọ̀, lákòókò àpèjọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ́lú àwọn adarí àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kan tí wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn iṣẹ́ tí ó fẹ́ ṣe ní ìparí àpèjọ Wọrld Bio, ọdún 2022.
Ó rọ̀ wọ́n láti jẹ́ aṣojú rere fún Nàìjíríà ni igba gbogbo.
Leave a Reply