Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pinnu láti ṣàtúnṣe lórí ìlànà ètò ibùgbé

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 253

Ìjọba Nàìjíríà ti ṣe àgbéyẹ̀wò  àdéhùn rẹ̀ lórí ìbáṣẹpọ̀ pẹ̀lú àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé, àjọ àgbáyé tó ń rísí ọ̀rọ̀ ibùgbé, UN-Habitat, lórí ìgbélárugẹ àtúnṣe iléégbé́ nínú ìlú, nípasẹ̀ ìmọ̀, ìmúlò àti ìrànlọ́wọ́ ìmọ̀-ẹ̀rọ

Mínísítà fún iṣẹ́ àti ibùgbé,Babatúndé Fáshọlá ṣe ìdánilójú yìí níbi ayẹyẹ kan ní Àbújá, olú-ìlú ní ìrántí àyájọ́ ibùgbé,ti ọdún 2022 pẹ̀lú Àkórí: “Fọkàn sí ààlà. Máá Fi ẹnìkan àti ibìkan sẹ́yìn. “

Ní ìfòpin sí ìpọ́njú àti àìdógba nípasẹ̀ ìmúse iṣẹ́ àwọn Mínísítà,Fáshọlá sọ pé ilé-iṣẹ́ ìjọba fún ètò iṣẹ́ àti ibùgbé pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ aládàáni ti ṣètò àtúnṣe lórí iṣẹ́ ṣíṣe ìlú àti àwọn ètò ìṣàgbéga Ìlú tí yóò pèsè iṣẹ́ tí ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin lọ fún àwọn ọ̀dọ́ Nàìjíríà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button