Ààrẹ Muhammadu Buhari ti ṣe afihan èróńgbà orílẹ̀-èdè Nàíjíríà láti fẹ ààyè ibasepọ ìṣòwò pẹ̀lú Orilẹ-ede Koria kọja àwọn ọjà òkèrè gáàsì.
Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ ni Seoul ní Ọjọ́rú lakoko ìpàdé àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ẹlẹgbẹ́ rẹẹ̀ ní Korean, Ọ̀gbẹ́ni Yoon Suk-Yeol ni Ile-igbimọ Ààrẹ ní bi àpéjọ àgbáyé àkọ́kọ́ (BIO), Ààrẹ Nàíjíríà pè fún ìmúgbòrọjà sí àdéhùn gáàsì ìgbà pípẹ́ àwọn agbègbè míràn.
Àwọn olùdarí méjèèjì tún jíròrò lórí ìwúlò ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní ìpele alápòpò, pàápàá ní Àjo Àgbáyé pẹ̀lú South Korea, wọn si tun ti n tọka si àyè láti du ìjókòó kan lori Ìgbìmọ̀ Ààbò ní ọdún 2024 àti wí pé wọ́n bẹ̀bẹ̀ fún àtìlẹyìn orílẹ̀-èdè Naijiria.