Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdíje Ife Ẹ̀yẹ Eré Bọ́ò̩lù Ilẹ̀ Áfíríkà – Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣèlérí Ètò Ààbò Tó Dájú

0 132

Kọmisana fún ọrọ Ọdọ ati Eré Ìdárayá ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seun Fakorede ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ pé àjọ tó n ṣe àkóso ere bọọlu alafese gba ní ilẹ Áfíríkà, CAF ati àjọ tó n ṣe àkóso idije ere bọọlu ni orílè èdè Nàìjíríà, NFF ti ṣe eto gbogbo fún abala eleekeji ife ẹ̀yẹ eré bọọlu ilé Áfíríkà, AFCON eléyìí tí yóò wáyé láàrin ẹgbẹ́ agba bọọlu oje wẹwẹ ọmọ orilẹ èdè Nàìjíríà tí ọjọ ori wọn kò ju ọdún mẹtalelogun (U 23) ati àwọn akeegbe wọn lati orílè èdè Tànsáníà ni ọjọ Àbámẹ́ta (29/10/2022) ni pápá iṣere Lekan Salami to kalẹ sí àgbègbè Adamasingba ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú ìpínlè Ọ̀yọ́ ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà .

Fakorede lo sọ èyí lásìkò tó n ba àwọn oníròyìn sọrọ lórí ìdíje ife ẹ̀yẹ náà ni Gbongan Dapo Aderogba ni ọgbà NUJ to wa ni agbegbe Iyaganku ni ìlú ìbàdàn. Ninu alaye rẹ, Komisana mẹnu ba oríṣiríṣi anfààní tó rọ mọ bi ìpínlè Ọ̀yọ́ ṣe jẹ́ olugbalejo fún ìdíje eré bọọlu náà, nígbà tí o tẹnu mọ pé ọrọ̀ ajé ipinlẹ Ọ̀yọ́ lapapọ yóò gbéra sókè ní pàtàkì jùlọ́, ẹka igbokegbodo ọkọ, àwọn oníṣòwò káràkátà ati àwọn onílé igbafe yóò jẹ anfààní alailẹgbẹ latari àwọn èèyàn ti yóò máa gúnlè sí ìpínlè Ọ̀yọ́ láti Ojo’bo (27/10/2022) lọ.

Àwọn oje wẹwẹ agba bọọlu ọmọ orilẹ èdè Nàìjíríà lo kọjú akeegbe wọn ni orilẹ èdè Tànsáníà ni ọjọ Àbámẹ́ta (22/10/2022) pẹlu àmì eyo kan sí odo (1-1). Orilẹ èdè tó bá jáwé olubori ninu Ifesewonse ti yóò wáyé ni ọjọ Àbámẹ́ta ni yóò tẹ síwájú sí ìpele tó kàn.

Ṣáájú nínú ọrọ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀ ní alága ẹgbẹ oníròyìn ní ìpínlè Ọ̀yọ́, Ademola Babalola ti lù Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seyi Makinde l’ogo ẹnu fún bí o ṣe pèsè àyíká to rọrùn láti lè jẹ kí ìpínlè Ọ̀yọ́ gba àlejò ìdíje náà.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.