Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Niger kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn tó fara káàsá ìjàǹbá ọkọ̀ ojú omi

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 272

Gómìnà Abubakar Sani Bello ìpìnlẹ̀ Niger ní arinwá-àárín Nàìjíríà ti kẹ́dùn pẹ̀lú àwọn ènìyàn  Lavun àti àwọn agbègbè ìjọba  Mokwa lórí Ìjàǹbá ọkọ̀ ojú omi tí ó yọrí sí pípádánù ẹ̀mí.

Gomina ninu ọrọ rẹ kan lati ọdọ agbẹnusọ rẹ ni ọjọ Abamẹta, Mary Noel  Berje, ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ajalu ati aburu.

O wa dupẹ lọwọ ile-iṣẹ to n risi pajawiri ni ipinlẹ Niger, (NSEMA) ati awọn ọmọ ẹgbẹ agbegbe omi fun ipa wọn ninu iṣẹ wiwa ati fun igbala  awọn olufaragba.

Bi o ṣe n kẹdun pẹlu awọn ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn, gomina ipinlẹ Niger ti paṣẹ fun awọn ile-iṣẹ to je mọ nnkan bẹyẹn lati gbe awọn igbesẹ to ṣe pataki lati yago fun iru ijanba bẹẹ nigba miran.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button