Take a fresh look at your lifestyle.

Ìpínlẹ́ Cross River Tí Pèsè Ibùdó Ẹrọ Ìgbàlódé Fún Kókó

0 77
Ìjọba Ipinlẹ Cross River tí pari èéto Ibùdó Ẹrọ ìgbàlódé tí à lè fi Kókó ṣé ní Ikom sì Ilé ìṣẹ AA Universal Agro  (AAU).

 

Gomina Ipinlẹ yìí, Ọjọgbọ́n Ben Ayade, nínú Iwe Ìfìmọ̀ṣọ̀kan tí wọ́n fọwọsi ni Gbọ̀ngàn ilé ìṣẹ rẹ ní Kálábá, ní ìdàgbàsókè yí jẹ ọkàn nínú àwọn ohùn tí ìṣejọba rẹ mọọ mọ ṣe láti dáa ọ̀rọ̀ ajé Ipinlẹ padà bọ̀ sípò.

 

Ayade sọ pé ìjàfárà léwu, ó kilọ fún àwọn ilé ìṣẹ náà láti gbé ìgbésẹ ní kíákíá láti bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ ni pẹrẹu, àijẹbẹ́ ilé ìṣẹ náà yóò dì ohùn ìtàn, nípa gbígbà àṣẹ ìdásilẹ̀ padà lọ́wọ́ wọ́n.

 

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ: “ile-iṣẹ Ibùdó Kókó láti fi dára oriṣiriṣi yìí jẹ ọkàn ninu ile-iṣẹ ti ijọba dáa silẹ gẹ́gẹ́ bí ara Ìpínnù wá lati dáa ile-iṣẹ ọlọ́kàn ó jọ́kàn silẹ ati ìfìmọ̀ṣọ̀kan lónìí sì ìdàgbàsókè ọ̀rọ̀ ajé Ìpínlẹ̀ Cross River;  ìfìmọ̀ṣọ̀kan yìí ni ó ń dárí ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ ajé kí ń ṣe idọ̀rẹ́.  Ìjọba n rètí láti rí Ibùdó tí ati n ṣe ohùn aládùn Ṣòkòlètì lati ọdọ ile-iṣẹ yìí láì pẹ láì jìnnà, lẹ́yìn oṣù mẹ́ta tí ile-iṣẹ yìí kò bá ṣe ohùnkòhùn, a ó bẹgi dínà ile-iṣẹ yìí á ó sì tíì pa.”

 

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ, ìfìmọ̀ṣọ̀kan yìí jẹ ifaga gbàgá Básá láàárín àwọn ilé ìṣẹ, kí AAU to jáwe Olubori, yàtọ si pe o jẹ ile-iṣẹ ibílẹ, wọ́n fi inifẹsi ikopa wọ́n han, wọ́n sì lọwọ nínú ìdíje Básá náà, látàrí èyí Alaga AAU, Ólóye Christopher Agara, fi dáwà lójú wí pé ile-iṣẹ náà yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ lẹsẹ kẹsẹ́, láì jáfárá.

 

O sọ pé, “Ohùn fí ń dá àwọn ọmọ Cross River àti gbogbo àgbáyé lójú wí pé awọ́n tí ní Ẹrọ Ìgbàlódé tí àwọn lè fí ṣé ohùn mèremère ti ó dára jùlọ tí gbogbo Àgbàye ati pápá àwọn ọmọ Cross River yóò fi yàngan-an láwùjọ, láàárín ọ̀sẹ̀ pérété tàbí Oṣù, a ṣetan láti jẹ kí ọjà wá di mímọ. A ó ní já yìn kú lẹ́, a ó ní dójú tiyín.”

 

Olubunmi Adeyẹmọ.
Leave A Reply

Your email address will not be published.