Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Mùhámádù Buhari Yóò Fi Oyè (OFR) Dá Ìgbákejì Gómìnà Bánkì Àgbà Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Tẹ́lẹ̀ rí Lọ́lá

0 76

Ààrẹ Mùhámádù Buhari yóò fi oyè (Officer of the order of the Federal Republic, OFR) da ẹni tíi ṣe igbákejì Gómìnà Bánkì Àgbà (CBN) ni orílè èdè Nàìjíríà tẹlẹ rí, Oloye Bayo Adelabu lọla ni ọjọ kọkànlá oṣù kẹwa ọdún yìí, (11/10/2022)

Olóyè Bayo Adelabu ti o ti fi ìgbà kan ri jẹ igbákejì gómìnà bánkì àgbà (CBN) tó tún jẹ Oludije du ipò gómìnà ni ìpínlè Òyó labẹ àsìá ẹgbẹ Accord (Accord Party) ni yóò darapo mọ awọn miran tí ìjọba apapọ ri wípé òye náà tó sì.

Ninu ìwé ìfitónilétí tí Mínísítà tó n rí sí Iṣé Pàtàkì ati Awọn iṣẹ Ìjọba Elekajeka (Minister for Special Duties and Intergovernmental Affairs), Amofin àgbà George Akume kọ tí o sì bù ọwọ lu jẹ kí o di mímọ̀ pé Ààrẹ Mùhámádù Buhari ti fi ọwọ sí í lati fi òye OFR, (Officer of the order of the Federal Republic) dá olóyè Adelabu lọla.

Ayẹyẹ ifoye-danilola náà ni yóò wáyé ní (International Conference Centre, ICC) ni ìlú Abuja tíì ṣe olú ìlú orilẹ èdè Nàìjíríà, ni ọjọ Isẹgun, ọjọ kọkànlá, oṣù kẹwa ọdún yìí (11/10/2022) ni déédé agogo mesan owurọ.

Abiola Olowe

Ibadan.

Leave A Reply

Your email address will not be published.