Take a fresh look at your lifestyle.

Ìkọ Àgbàbọ́ọ̀lù England Ṣubú Yakata Sọwọ́ Ìkọ Àgbàbọ́ọ̀lù Italy

0 81

Agbàbọ́ọ̀lù England pàdánù 1-0 sí ìkọ àgbàbọ́ọ̀lu Italy ni Milan, nínú ìdíje UEFA Nations League. Ìfìdí rẹmi yìí lò jawọn bọ̀ lórí akasọ kínní sì ipò ọwọ isalẹ nínú tábìlì akasọ.

Giacomo Raspadori ló fà awọn yà ní San Siro ní iṣẹju mejidinladọrin (68mins). Tí ifidi rẹmi ìkọ England ṣí n tẹ̀síwájú ní ifẹsẹwọnsẹ márùn, àkọkọ́ irú rẹ̀ l’ọdun Mẹjọ.

Akoni-mọọgba orile-ede England Gareth Southgate fí ọkàn balẹ lórí Harry Maguire botilẹjẹpe ẹsẹ rẹ̀ kò múlẹ mọ nínú ìkọ Manchester United bi ati ẹyin wa.

Ìkọ England gbìyànjú láti daá padà ṣùgbọ́n aṣọlè ìkọ Italy Gianluigi Donnarumma ṣé ṣẹ ribiribi bó ṣe dá bọ́ọ̀lù Harry Kane dúró. Bẹẹ, ìkọ Italy náà tún gbìyànjú onírúurú ki ifẹsẹwọnṣe náà tó wà sí òpin.

Lekan Orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.