O kéré jù, ènìyàn ẹrindinladọrun ló tí dagbere faye lẹyìn tí ìjàmbá ọkọ ojú omi ti wón fi n rìn ìrin àjò dànù ni etikun Síríà (Syria). Nigbati ogun mìíràn n gbà ìtọjú ní ilé ìwòsàn ti wọn ṣí n wà àwọn àrin rìn àjò toku ni òkun.
Awọn òṣìṣẹ́ ojú omi sọ pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Lebanoni, Siria ati Palestine ní wọ́n wà nínú ọkọ náà ti awọn obinrin ati ọmọde wa laarin awọn ènìyàn tí ìyè wọn kò kéré sí aadọjọ. Kò sí ẹní tí o mọ́ òun tó fà iṣẹlẹ burúkú náà. Wọn tún fí ìdí rẹ múlẹ̀ pé ọkọ ojú omi náà ló gbéra ní Minyeh, Lebanon ni ẹgbẹ Tripoli ṣáájú kí o tó ri sí erékùṣù Síríà tí Arwad, ní tosí Tartus.
A gbàgbọ́ pé ọkọ ojú omi náà ló nlọ sí Cyprus ṣiwaju kí o tó rí. Àwọn òkú ti kò ní wón ti gbe fún àjọ Red Cross tí ilẹ̀ Lebanoni.
Gẹgẹ bí Àjọ UN ṣé sọ, àwọn tó n gbìyànjú láti kọjá omi lati orílẹ-èdè wọnyí ti ọdún 2021 ló fẹrẹ lọpo meji tí ọdun 2020. Bẹẹ, ní ti ọdún yíì tí kọjá àwọn ọdún méjèèjì yìí níbí ti ọdún yíì dé dúró.
Ní ìbẹrẹ oṣù yìí, ènìyàn mẹfa pẹlú àwọn ọmọdé, tí pàdánù èmi wọ́n nígbà tí ọkọ ojú omi tó gbé wọn rí sí etikun Turkey nígbà tí wọn lọ sí Yúrópù.
Àwọn olùṣọ etikun tí orílẹ̀-èdè náà sọ pé awọn àrin rìn àjò to tó ẹtalelaadọrin (73) ní wọ́n tí gbàla lójú omi nínú ọkọ merin.
Lekan Orenuga
Leave a Reply