Take a fresh look at your lifestyle.

Egipti Pinnu Láti Gbá Àlejò Ìdíje Òlímpíkì ní ọdún 2036

0 108

Mínísítà ọdọ àti àwọn èré ìdárayá tí orílẹ-èdè Egipti, Ashraf Sobhi sọ pé Egipti yóò bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbálejo èré Òlímpíkì ní ọdún 2036.

Mínísítà náà sọ pé ti ìbéèrè náà bá yọrí sí bí atifẹ, Egipti yoo jẹ orílẹ̀-èdè Arab àkọkọ́ tàbí orílẹ-èdè Áfíríkà tí yóò gbà àlejò ìdíje òlímpíkì naa.

Ọgbẹni Ashraf l’akoko to n gbà àlejò Alàkóso Ìgbìmọ̀ Òlímpíkì Káríayé Thomas Bach ní Cairo sọ pé Àárẹ̀ Abdel Al-Sisi fi ọwọ sí.

Bach ni tirẹ̀ so wípé orile-ede náà ni awọn òun èlò ere idaraya ti won sì lágbára láti gbà àlejò ìdíje náà nígbà tí o ṣé àbẹwò sí àwọn orílẹ̀-èdè èdè náà.

Nibayìí , Òlímpíkì yóò wáyé ní Ìlú Paris ní ọdún 2024, tí Los Angeles orílẹ-èdè Amẹ́ríkà yóò gbà àlejò ní 2028 àti Brisbane, Australia ní 2032.

Sibẹsibẹ, ìlànà ati ètò tá ní yóò gbalejo ìdíje Òlímpíkì 2036. Tí àwọn orílẹ̀-èdè bíi Germany, Mexico, Turkey, Russia, India, ati Qatar náà ni ànfàní láti gbalejo.

Lekan orenuga

Leave A Reply

Your email address will not be published.