Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ Yàgò Fún Àwọn Oníjìbìtì Orí Ẹ̀rọ Ayélujára: SUBEB Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣe Ìkìlọ̀

0 91

Ilé Iṣé to n mójú tó ètò ẹkọ káríayé ni ìpínlè Òyó (OYOSUBEB) ti kìlọ fún àwọn tó n wa iṣẹ láti yàgò fún àwọn onijibiti orí ẹrọ ayélujára tó n kéde ààyè igbani ṣíṣe fún ọdún 2022.

Ninu atejade láti ọwọ alaga ile iṣẹ náà, Ọmowe Nureni Adeniran ti sọ fún gbogbo awọn ti ọrọ náà bawi wípé iro tó yàtọ sí òtítọ ni irú ìkéde bẹ́ẹ̀.

Adeniran wá gba gbogbo ẹni tó n wa iṣẹ láti ṣọra fún irú àwọn onijibiti orí ẹrọ ayélujára tí wọn n paro pe àwọn n ṣiṣe fún ijoba, ti o sì sàlàyé pé tí àsìkò ba to fún ìjọba ìpínlè Òyó láti gba eyan ṣíṣe, ilé iṣẹ SUBEB yóò fi ìkéde síta.

Alága SUBEB tún kìlọ fún àwọn tó n wá iṣẹ láti máṣe sàn owó kankan fún ẹnikẹ́ni láti orí ẹ̀rọ ayélujára. O wa tẹnu mọ pé àjọ SUBEB ipinle Òyó yóò gba ònà ẹtọ láti gba àwọn eyan sí iṣẹ yato sí ònà jibiti orí ẹrọ ayélujára to wa níta lásìkò yí.

 

Abiola Olowe

Ibàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.