Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Àdàrí Ẹ̀gbẹ́ Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà gbé ijẹniniya Lórí Ìjọba Alatako Guinea

0 212

Gẹ́gẹ́bí iṣé orílẹ̀-èdè Málì ní ìsàmì sí ọjọ́ òmìnìra tó wáyé ní Ọjọ́bọ̀ ní iwájú Olórí Ìjọba Ológun Guinea, Col Mamady Doumbouya, tí àwọn Olùdarí Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà wà ní ìpàdé pajawiri kàn ní New York, níbí Àpéjọ Ìgbìmọ̀ Orílẹ-èdè Àgbáyé (UN General Assembly).

Wọ́n gbà ní ìpàdé pajawiri náà láti gbé ìgbésẹ tó lè díẹ̀díẹ̀ lórí ìjọba ológun tí Guinea lórí bí wọ́n ṣé kùnà láti dá àgbàrá pàdà fún ìjọba tiwa-n-tiwa.

Lakotan ipade ẹ̀gbẹ́ orílẹ-èdè Ìwọ̀-Oòrùn Áfíríkà tí ń jìjàkadì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdìtẹ̀ gbajọba àwọn ológun ní ẹkùn náà ní ọdún méjì sẹ́yìn. Ìdí níyì tí ìpàdé pajawiri náà ṣe wáyé ti ijẹni-nípa náà yóò fí máà ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n ṣé àtìlẹ́yìn fún ìjọba Guinean náà.

Málì ní Ológun fí ipá gbà ìjọba ní Oṣù Kẹjọ ọdún 2020 àti Oṣù Karun 2021, tí Guinea wáyé ní Oṣù Kẹsán 2021 ati Burkina Faso ní Oṣù Kíní ọdún kàn náà.

Ẹ̀gbẹ̀ orílẹ̀-èdè ìwọ̀-oòrùn (ECOWAS) tí n ṣé àmójúkúrò ijẹni-níyà lile tí wọ́n gbé kalẹ fún ijọba ologun Mali nígbàtí wọ́n ti gbà dá ìjọba padà sí tiwa-n-tiwa ní Oṣù Kẹta ọdún 2024.

Málì àti Guinea ló tí gbà ìwé gbélé-ẹ làti ọwọ àjọ ECOWAS.

ECOWAS tí bú ẹnu àtẹ lù bí wọ́n ṣe tí àwọn ọmọ Ogún orílẹ̀-èdè Ivory Coast kàn mọle àti pé o tí pinnu láti ràn àwọn Ààrẹ tí Ghana, Togo ati Senegal lọ sí Mali láti gbà itusilẹ wọ́n ní ọjọ́ Ìṣẹgun, Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn Oṣù Kẹsán.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button