Take a fresh look at your lifestyle.

Agbára Nínú Ìṣọ̀kan: Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Ṣe Àlàkalẹ̀ Ètò Fún Àyájọ́ Ọjọ́ Òmìnira Orílẹ̀-èdè Nàìjíría

0 234

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti la awọn ètò olokan-ojokan kalẹ ni ìgbáradì fún ayajọ ọjọ tí orilẹ èdè Nàìjíríà gba òmìnira, pẹlu àkòrí tó sọ pé ‘Agbara Nínú Iṣọkan’

Ẹni tíi ṣe Komisana fún òrò Ọdọ àti Eré Ìdárayá ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Seun Fakorede lo sọ èyí nínú atẹjade kan tí o fi ṣọwọ́ sí àwọn oníròyìn ní ìlú ìbàdàn tí ì ṣe olú ìlú ìpínlè Òyó ní ẹkùn gúsù iwọ oòrùn orilẹ èdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bíi àlàyé rẹ̀, Fakorede je ki o di mímọ pé ayajọ ọdún kejilelogota ti orilẹ èdè Nàìjíríà gba òmìnira ti ọdún yìí yóò bèrè pẹlu ètò ìsìn pàtàkì ni ijọ St Peters Aremo ni ìlú Ìbàdàn ni ọjọ keedogbon osu yìí (25/09/2022) ni déédé agogo mesan owurọ nibi ti àwọn ẹlẹsin kristeni ninu àwọn olóṣèlú àti onísé ìjọba yóò ti péjú láti gbàdúrà fún ilẹ wa.

Bákan náà, ìpàdé pàtàkì pẹlu awọn ọdọ yóò wáyé ní aago mewa aaro ọjọ́ ajé (26/09/2022) ní ilé igbimọ Aṣòfin Ìpínlè Òyó. Nígbà tí àwọn ọmọ ilé èkó alakobere àti girama náà yóò máa fi igba gbágà pẹlu ara wọn nínú ìwé kíkọ ni yàrá ìpàdé ile iṣẹ tó n darí ètò Ẹkọ, Sáyẹnsì àti Ìmọ Ẹrọ ni ipinle Òyó, ni owurọ ọjọ Isẹgun (27/09/2022).

Atejade naa tun fi hàn pé àwọn oṣiṣẹ ọmọ ológun ni ipinle Òyó náà yóò ṣe eré ìjàkadì ti wọn yóò sì tún ta ‘ayò olópón’. Bákan náà ni ‘irin òmìnira’ ní ọjọ’ bọ (27/09/2022), pẹlu awọn tó di ipò òṣèlú kan tàbí òmíràn mú, awon àgbà oṣiṣẹ ìjọba, oṣiṣẹ OYRTMA, MAN-O-War, awọn ẹṣọ ojú pópó, FRSC ati awọn miran yóò bèrè ní déédé agogo mẹwa owurọ.

Bẹẹni ìsìn Irun Jumat pàtàkì yóò wáyé ni ọjọ Etì (30/09/2022) ni déédé agogo kan osan pẹlu awọn mùsùlùmí òdodo láti gbàdúrà fún orilẹ èdè Nàìjíríà. Nígbà tí asekagba eto naa yóò wáyé ni ọjọ́ Àbámẹ́ta (01/10/2022) ni pápá iṣere Lekan Salami to kalẹ sí àgbègbè Adamasingba ni ìlú ìbàdàn ni déédé agogo mẹjọ owurọ.

Komisana wa rọ àwọn òbí àti alágbàtọ jakejado ìpínlè Òyó láti jòwó àwọn ọmọ wọn láti darapọ mọ́ ètò náà fún yíyan bíi ológun. O sì fi dá àwọn òbí àti alágbàtọ lójú wípé ààbò tó péye yóò wá fún àwọn ọmọ wọn, ti ilé ẹkọ tó bá peregede yóò si gba ẹbun relé.

 

Abiola Olowe
Ibàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button