Take a fresh look at your lifestyle.

Ìbásepọ̀ Ọrọ̀ Ajé Tí Ó Múná Dóko Se Pàtàkì Pẹ̀lú Orílẹ̀ Èdè Amẹ́ríkà

0 47

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti se àpèjúwe ìbásepọ̀ ọrọ̀ ajé tí ó wà láàrin orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà pẹ̀lú Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó gbajúmọ̀, tí ó sì dán mánrán. Ó sì se pàtàkì láti ríi pé ìbásepọ̀ náà tẹ̀ síwájú láti mú àlékún bá ọrọ̀ ajé ilẹ̀ Nàìjíríà.

 

Ààrẹ fi ọ̀rọ̀ náà léde níbi ìpàdé àpérò lórí ọrọ̀ ajé ẹlẹ́ẹ̀kẹrìndínlọ́gọ́rin irú rẹ̀ tí ó wáyé ní ìlú Newyork ní ọjọ́bọ̀ osù kẹẹ̀sán ọdún 2022.

 

Ààrẹ Buhari se àpèjúwe orílẹ̀ èdè Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ọrọ̀ ajé rẹ̀ tòbí jù ní ilẹ̀ adúláwọ̀, èyí ló fún un ní ànfààní láti kó ipa tí ó yanjú nínú ètò ọ̀gbìn, Ìlera, Ohun amáyédẹrùn àti ìdàgbàsóke ìmọ̀ ẹ̀rọ.

Leave A Reply

Your email address will not be published.