Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Isẹ́ Ìfìwé Ráńsẹ́ Ní Adarí Titun

0 56

Mínísítà fún ètò ìbá araẹni Sọ̀rọ̀ , ọ̀jọ̀gbọ́n Isa pantami ti bu ọwọ́ lu ìyànsípò ọ̀gbéni Bulus Yakubu gẹ́gẹ́ bíi  adelé titun ilé isẹ́ ìfìwé ráńsẹ́ àpapọ̀ ilẹ̀ Nàìjíríà, lẹ́yìn tí wọ́n ti já ewé gbélé rẹ fún Dókítà Ismail Adebayọ.

 

Yakubu, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Takum, ní ìbílẹ̀ Takum, ìpínlẹ̀ Taraba. Ó jẹ́ amòfin, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé àgbà ní ilé isẹ́ ìfìwé ráńsẹ́ náà saájú ìyànsípò rẹ̀.

 

Ó jẹ́ ẹni tí ó kójú òsùwọ̀n, àtipé òsìsẹ́ ìjọba tí ó ní ìrírí ni yakubu jẹ́.

Leave A Reply

Your email address will not be published.