Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ti Pè Fún Ìdáàbòbò Ìsẹ̀lẹ̀ Omíyalé

0 65

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin ti ké sí ẹka ìjọba tí ó wà fún àmójútó àyíká láti ríi pé wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tí ó yẹ láti dènà omíyalé. Ìpè yí wáyé lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ omi ti dá ẹ̀mí àwọn ènìyàn ní ògbodò, tí ó s̀i ba ọ̀pọ̀ oko àti dúkìá jẹ́ ní ìlú jigawa, Kano àti àwọn ìpínlẹ̀ mínràn ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

 

Wọ́n pè fún àmójútó ojú ọ̀nà omi àti ẹ̀kọ́ tí ó péye láti dènà irú ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.

 

Àgbájọpọ̀ ilé pèpè fún síse ìgúnpá àti ìrànlọ́wọ́ fún àgbègbè tí ìsẹ̀lẹ̀ ìjàm̀bá omi náà sẹlẹ̀ sí àti ìtọ́jú tí ó péye fún àwọn tí ó fi ara káásá níbẹ̀, láti ọ̀dọ̀ ìjọba. Wọ́n sì rọ ìjọba ìpínlẹ̀ tí ọ̀rọ̀ náà kaǹ láti wá ọ̀nà àbáyọ sí irú wàháĺà bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ iwájú.

Leave A Reply

Your email address will not be published.