Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ìgbìmọ̀ Asòfin Ìpínlẹ̀ kogí Dá Dangote Ní Ọwọ́ Kọ́ Ní Ìbílẹ̀ Méjì

0 60

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Kogi ti pa àse fún ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà láti dá ilé isẹ́ Dangote dúró ní ìjọba ìbílẹ̀ olamaboro àti Ankpa ní ìpínlẹ̀ Kogi.

 

Eléyìi ́kò sẹ̀yìn ìpalára tí ilé isẹ́ náà ń kó bá àwọn ènìyàn àti àyíká nípa wíwa kùsà. Kọlawọle fi ọ̀rọ̀ náà léde pé, ilé isẹ́ Dangote kò bìkítà nípa àlàáfíà àti ìgbáyégbádùn àwọn ènìyàn àgbègbè náà léyìí tí ó sì ń rí òbítíbitì owó ní àwùjọ náà.

 

Ìgbésẹ̀ náà wáyé lẹ́yìn tí ilé isẹ́ náà ti kùnà láti jẹ́ ìpè ilé ìgbìmọ̀ asòfin, léyìí tí ó pa àsẹ pé, ilé isẹ́ náà gbọdọ̀ fi ara hàn ní tipá-tipá ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n osù kẹẹ̀sán ọdún 2022.

Leave A Reply

Your email address will not be published.