Bí ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe ń súnmọ́ etílé náà ni ìgbáradì ń lọ ní pẹrẹu.
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò pe ọdún méjìlélọ́gọ́ta ní ọjọ́ kínní, Oṣù Kẹwàá ọdún 2022. Àwọn ológun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lápapọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní gbáradì fún ayẹyẹ náà
Ìgbáradì ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹẹdogun oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022, yóò sì parí ní ọjọ́ tí o gbẹ̀yìn oṣù yìí.
Díẹ̀ lára àwọn ológun àti àwọn tó farapẹ́ ológun tí o kópa nínú ìgbáradì náà ni ̀áwọn ikọ ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ologun ori omi Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ológun orí afẹfẹ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Àwọn agbofinro , àwọn Òṣìṣẹ́ alaabojuto ọgba ẹwọn, àwọn ẹ̀ṣọ́ ojú ọ̀nà, àwọn ẹ̀sọ́ fún eto ìwé ìrìnà, àwọn àgùnbánirọ̀, àti àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ mìíràn.
GEORGE ỌLÁYINKÁ AKÍNTỌ́LÁ.
Leave a Reply