Take a fresh look at your lifestyle.

Ètò Mọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà Di Ìrọ̀rùn Ní Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà

0 50

Àjọ tí ó ń se àkóso ìlú Àbújá ti wá ojúpọ̀nnà láti ri dájú pé ètò mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà di ìrọ̀rùn fún ará ìlú. Adarí àgbà ní ẹka ètò ẹ̀kọ́, Hajia Hajarat Alayande sàlàyé ọ̀rọ̀ náà pé, àmúgbòòrò ti bá ètò ẹ̀kọ́ tí ó sì mú ọ̀nà ìkọ́sẹ́ ọwọ́ rọrùn fún mùtúmùwà.

 

Ó sàlàyé síwájú pé, ètò náà wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ààrẹ Mulammadu Buhari láti rí dájú pé, ètò ìlé ìsẹ́ wọ̀ gbẹ́ fún mílíọ̀nù mẹ́wàá ọmọ Nàìjíríà wá sí ìmúsẹ.

 

Arábìnrin náà gbé òsùbà fún Mínísítà  ìlú Àbújá, Mallam Muhammed Bello fún akitiyan rẹ̀, àtipé ètò náà yóò mú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ gbòòrò síi tí yóò sì pèsè isẹ́ ọwọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè wa.

Leave A Reply

Your email address will not be published.