Take a fresh look at your lifestyle.

Opẹ́ o! Olosere Jim Iyke Jẹ Oyè Ní Orílẹ̀ Èdè Ghana

0 72

Gbajúmò òṣèré nì , Jim Iyke ni wọ́n ti fi jẹ òye tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “OHADIKE 1 OF NDIGBO” láti ọwọ́ HRH Dr AMB. Chuwudi J Ihenetu, Ezi Ndibgo Ghana,   dáa lọ́lá ní orílè-èdè Ghana.

Oyè  náà ni wọ́n fi dáa  lọ́lá ní àyájọ́ ọdún Iṣù wọn tí o wáyé ní ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹ̀sán án, ọdún 2022.

Bí HRH Dr AMB. Chuwudi J. Ihenetu, se ṣọ, ó ní wọn fi òye náà dáa Lola fún imoriri iṣẹ́ takuntakun, àseyege àti ìfaraẹnijì rẹ̀ fún ilẹ̀ Adúláwọ̀ àti àwọn ẹ̀yà Igbo lápapọ̀.

Arákùnrin ọmọ ọdún márún dín ladota náà, James Ikechukwu Esomugha, ti wọ́n mọ̀ sí, Jim Iyke, jẹ́ òṣèré àti Olùdarí eré ní orílè èdè Nàìjíríà.
Ó tilẹ̀ gbé eré alárinrin kan jáde ní ọdún 2021 tí àkòrí rẹ̀ ń jẹ́ “Ijẹ́rìí Búburú” – ‘Bad Comments’ .

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave A Reply

Your email address will not be published.