Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Iṣẹ́ Ìgbóhùn Sáfẹ́fẹ́ Fọwọ́sowọ́pọ̀ Pẹ̀lú Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ Fún Ìpèsè Ètò Ẹ̀kọ́ Tó Yanrantí

0 58

Gbajúgbajà ilé Iṣẹ́ igbohun safefe kan ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti fi èròngbà rẹ hàn pé òun ti ṣetan láti fowosowopo pẹ̀lú ìjọba ìpínlè Òyó fún idasilẹ ètò ẹkọ onimọ ẹrọ.

Ẹni tíi ṣe Olórí ẹkùn gúsù iwọ oòrùn ilé iṣẹ Agbohun safefe Globacom, Adéwálé Adiatu ló ṣe afọmọ ọrọ yìí ni ọfisi Alága to n ri sí ìpèsè Ètò Ẹkọ Kari ayé níbi tí o salaye pàtàkì ẹkọ to yanranti gẹgẹ bí ònà lati mu ojutu de ba ìṣòro àwùjọ.

Adiatu wá sọ dájú wípé, ilé iṣẹ agbohun safefe Globacom ni onírúurú awọn ohun èlò láti fi kẹkọọ lórí ẹ̀rọ ayélujára ati wipe ilé iṣẹ náà ní ìgbàgbọ pé pe ìjọba ìpínlè Òyó yóò mú ànfààní náà lo.

Nigba tí o n feesi, Alága Ètò Ẹkọ Kárí ayé ni ìpínlè Òyó, Ọmowe Nureni Adeniran jẹ kí o di mímọ pé ìjọba ìpínlè Òyó mu ọrọ ètò ẹkọ lokunkundun ti o sì n gbiyanju lati rí dájú wípé gbogbo ọmọ ló ni oore ọfẹ ẹkọ tó yè kooro jake jado Ìpínlè Òyó.

Adeniran tun tẹnu mọ pé ìpínlè Òyó náà mọ pàtàkì ẹkọ, ti wọn sì ṣetan láti lò gbogbo anfaani ti ẹkọ nípa imo ẹrọ mú wá fún àṣeyọrí gbogbo ọmọ ni ìpínlè Òyó. O wa fi àsìkò náà dà ile iṣẹ agbohun safefe náà lójú pé ìjọba tí ṣetan láti bá ilé iṣẹ Globacom àti ilé iṣẹ́ yoowu tó bá fẹ bá wọn da owo pọ fún ìpèsè ẹkọ tó yanranti.

Abiola Olowe
Ibàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.