Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ NGO Pè Fún Ìpè Àlààfíà Ní Gbogbo Orílẹ̀ Èdè

0 231

 

Àjọ tí kìí ṣe ti Ìjọba, the International Society of Media in Public Health (ISMPH) ti rọ gbogb àgbáyé láti jẹ́kí àlààfíà jọba. Ó sọ pé àlààfíà jẹ́ ìgbìyànjú àpapọ̀, kí a gba àlààfíà láàyè.

 

Èyí wà nínú ọ̀rọ̀ kan tí ó jẹyọ ní ojó Ọjọ́rú láti ọ̀dọ Olùdarí àti olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ kan, Ìyáàfin Mojí Makànjúọlá lórí ayeye Ọjọ́ Àlààfíà Káríayé.

 

Olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ àti Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn obìnrin oniroyin, National Association of Women Journalists(NAWOJ), fi kun pé; Ó jẹ́ ojúṣe gbogbo ènìyàn láti jẹ́kí àlààfíà jọba èyítí ó sọ pé yóò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ sí ipò ọpọlọ pípé ti gbogbo ènìyàn ní àyíká wa.

 

Ọjọ́ àlààfíà Káríayé ni wọ́n fi lọ́lẹ̀ ní ọdún 1981 tí a sì ń se àkíyèsí àti ayẹyẹ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ kọkànlélógún, Oṣù Kẹsàn ọdọọdún káàkiri gbogbo àgbáyé.

 

Ọjọ́ kan ni gbogbo àgbárí-jọpọ̀ àgbáyé yà sọ́tọ̀ fún àlààfíà tí gbogbo àgbáyé sì ń bọ̀wọ fún ọjọ́ náà tí kò gbọdọ̀ sí ogun, ìpáǹle tàbi wàhálà Kankan kárí ayé.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button