Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ Fáfitì Lápapọ̀ Pé Ìpè Láti Mase Fòpin Ṣí Ìyansẹ́lódì Ní Ilé Ẹjọ́

0 36

Àjọ Fáfitì Lápapọ̀ (ASUU) ti sọ fún agbẹjọro rẹ, Ògbéni Femi Falana, láti
rọ ilé ẹjọ láti máṣe fopin ṣí Ìyansẹ́lódì olosù méje rẹ tó ń lọ lówó nítorí ilẹ ẹjọ́ gíga orílè- èdè yìí’ tí kàńpá fún wọn láti so Ìyansẹ́lódì rọ̀.

Eléyìí di mímọ̀ fún ilé iṣẹ Voice of Nigeria láti ọwó akòwé àgbà ti Committee Of Vice Chancellors of Nigerian Universities (CVCNU), Ọjọgbọn
Yakubu Ochefu ni alẹ́ ọjó ọjọ́rú nígbàtí ìgbẹ́jọ́ náà parí.

Ojogbon Yakubu Ochefu sọ wípé àjọ ASUU jẹ àjọ tí yoo gbọ́ràn ṣí àṣẹ ìjọba nígbàtí o bá ń já fún ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ, yóò sì rí wípé gbogbo rẹ yọrí si èbúté ogo nigbati won ba n rọ ilé ẹjọ lati se ohun ti wọn fẹ ni ọjó Ọjọ́bọ̀.

Ilé Ìṣẹ́ Voice of Nigeria gbìyànjú láti bá Alága ASUU ,Comrade Emmanuel Osodeke sọrọ léyìn ìgbẹ́jọ́ ọjó ọjọ́rú, sùgbón pàbó ló já sí.

. Àwọn omo ẹgbẹ́ ASUU bẹrẹ Ìyansẹ́lódì ní ọjó Kẹrìnlá, oṣù Kejì ọdún yìí lórí gbígba wọlé ètò Integrated Personnel Payroll Information System (IPPIS) ti  Ìjọba gégébí ọ̀nà tí ìjọba fẹ lò láti máa sanwó fúnwọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkàn míràn tí wón tún n bèrè lówó ìjọba tí ìjọba kòsí ti dáwọn lohùn tí àwọn náà kòsí padà sẹ́nu Isẹ́ wọn.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.