Take a fresh look at your lifestyle.

2023: Àwọn Ọmọ Ẹgbẹ NNPP Mẹ́rin Kéde Ìdarapọ̀ Wọn Mọ́ Olùdíje Ààrẹ Ẹgbẹ́ APC

0 57

Ní ọjọ ọjọ́rú, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ New Nigeria Peoples Party (NNPP) mẹ́rin ní Ìpínlè Ọ̀sun kéde ìsàtìlẹ́yìn Òǹdíje Ààrẹ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC,  Ọ̀gbẹ́ni Senator Bọ́láTinúbú.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ mẹ́rin ọ̀hún nìyì:
Clement Bamigbola, láti Osun Central Senatorial candidate; Bolaji Akinyode, Osun West Senatorial zone; Olalekan Fabayo àti Oluwaseyi Ajayi ti Boluwaduro/Ifedayo/Ila, àti Ijesa South Federal Constituencies bakanna.
Wọ́n gbé ìgbésẹ yìí nítorí wọn kò ní ìgbàgbọ nínú Òǹdíje Ààrẹ NNPP , Senator Rabiu Kwankwaso mọ́ àti bí ó se ń ndari wọn látòkè wá kò jẹ́ kó yé wọn.

Nígbàtí ó n bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní Òsogbo, Ọ̀gbẹ́ni Bamigbola fi léde pé gbogbo àwọn nkan tó n ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ wọn tí wọn kò fẹ pàápàá latọ̀dọ̀ olórí wọn ló jẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ akin náà, àwọn alátilẹyìn wọn ṣì ti ní kí wọ́n máa lọ, àwọn wá léyìn wọn bí iké.

Ó fi kun pé, ìṣàkóso àti ìjọba rere pẹ̀lú mùndùnmúndùn ìjọba àwarawa yóò jẹ́ tiwọn lábẹ́ ìjọba Ààrẹ Tinubu tí ó bá leè wọlé .

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.