Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ilé Iṣẹ́ Mottainai Yóò Ṣe Àgbékalẹ̀ Ibùdó Tó ń ṣe Àtúnrọ Ike Àti Páálí Àlòkù Jákèjádò Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

0 75

Ilé Iṣẹ́ agbase ṣe kan ni ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Mottainai Recycling Ltd. ti sọ wípé òun yóò ṣe àgbékalẹ̀ awọn ibùdó keekeekee ti yóò máa ṣe atunro awọn aloku ike, páálí àti àwọn ọra omi sí ohun èlò tuntun míràn (recycling hubs) jakejado ìpínlè Òyó. Nígbà tí o sọ di mímọ̀ pé Ọjà Anajeere ni akọkọ irú ibùdó náà.


Ọgbẹni Adey Adewuyi tíì ṣe Olùdarí ilé iṣẹ Mottainai Recycling lo tẹnu mọ pe idasilẹ awọn ibùdó tó n ṣe atunro wọnyi yóò mú ojútùú dé bá ipenija ti ará ìlú n kọjú, bákan náà bi ṣíṣe atunro awọn ohun tí a ti lo ku wọnyi dì tuntun míràn ṣe n sọni di ọlọrọ.

Adewuyi tun tẹnu mọ nínú ọrọ rẹ pe ile iṣẹ òun se àwárí awọn ike aloku oni kilogiramu Ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lé lẹẹdọọgọ́sán àti páálí kilogiramu Ẹ̀ẹ̀dẹ́gbẹ̀fá lásìkò tí wọn n ṣe ayẹyẹ Ọjọ Ìmọ́tótó L’agbaye ti ọdún 2022, eleyii tii ṣe akọkọ irú rẹ ti ile iṣẹ Mottainai se ni ìlú Ìbàdàn.

Adewuyi tun sàlàyé wípé ilé iṣẹ́ òun tún ṣe ètò koriya nípa fífún ẹni tó bá b’awọn ko aloku ike àti páálí ní ẹbun. Nínú èyí tí ilé iṣẹ́ náà fi ṣe iyikoto lati jẹ ẹbun tí Abileko Nofisat Oguntade sì gba ẹbun sare ilẹ kan.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave A Reply

Your email address will not be published.